-
Léfítíkù 3:3-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Kó fi lára ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà:+ ọ̀rá+ tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká 4 àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú rẹ̀. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ ẹran náà. 5 Kí àwọn ọmọ Áárónì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ, lórí ẹbọ sísun tó wà lórí igi lórí iná;+ ọrẹ àfinásun tó ní òórùn dídùn* ló jẹ́ sí Jèhófà.+
-
-
Léfítíkù 7:29-31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ mú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún Jèhófà mú ọrẹ wá fún Jèhófà látinú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀.+ 30 Ọwọ́ ara rẹ̀ ni kó fi mú ọ̀rá+ pẹ̀lú igẹ̀ wá láti fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, kó sì fì í síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì+ níwájú Jèhófà. 31 Kí àlùfáà mú kí ọ̀rá náà rú èéfín lórí pẹpẹ,+ àmọ́ igẹ̀ náà jẹ́ ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀.+
-