ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 35:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Nígbà kan tí Ísírẹ́lì ń gbé ilẹ̀ yẹn, Rúbẹ́nì lọ bá Bílíhà tó jẹ́ wáhàrì* bàbá rẹ̀ sùn, Ísírẹ́lì sì gbọ́ nípa rẹ̀.+

      Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù jẹ́ méjìlá (12).

  • Jẹ́nẹ́sísì 49:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Torí ara rẹ kò balẹ̀ bí omi tó ń ru gùdù, o ò ní ta yọ, torí pé o gun ibùsùn+ bàbá rẹ. O sọ ibùsùn mi di ẹlẹ́gbin* nígbà yẹn. Ó gun orí rẹ̀!

  • Léfítíkù 20:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ọkùnrin tó bá bá ìyàwó bàbá rẹ̀ sùn ti dójú ti* bàbá rẹ̀.+ Ẹ gbọ́dọ̀ pa àwọn méjèèjì. Ẹ̀jẹ̀ wọn wà lórí wọn.

  • Diutarónómì 27:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá bá ìyàwó bàbá rẹ̀ sùn, torí ó ti dójú ti bàbá rẹ̀.’*+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)

  • 2 Sámúẹ́lì 16:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Áhítófẹ́lì wá sọ fún Ábúsálómù pé: “Bá àwọn wáhàrì* bàbá rẹ lò pọ̀,+ àwọn tó fi sílẹ̀ pé kí wọ́n máa tọ́jú ilé.*+ Gbogbo Ísírẹ́lì á wá gbọ́ pé o ti sọ ara rẹ di ẹni ìkórìíra lójú bàbá rẹ, ọkàn gbogbo àwọn tó ń tì ọ́ lẹ́yìn á sì balẹ̀.”

  • 1 Kọ́ríńtì 5:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Ní tòótọ́, wọ́n ròyìn ìṣekúṣe*+ tó ṣẹlẹ̀ láàárín yín, irú ìṣekúṣe* bẹ́ẹ̀ kò tiẹ̀ sí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé ọkùnrin kan ń fẹ́* ìyàwó bàbá rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́