-
Diutarónómì 27:22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá bá arábìnrin rẹ̀ sùn, ì báà jẹ́ ọmọ bàbá rẹ̀ tàbí ọmọ ìyá rẹ̀.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
-
-
2 Sámúẹ́lì 13:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ámínónì wá sọ fún Támárì pé: “Gbé oúnjẹ* náà wá sínú yàrá mi, kí n lè jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Torí náà, Támárì gbé kéèkì tó rí bí ọkàn tó ti ṣe wá fún Ámínónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ nínú yàrá. 11 Nígbà tó gbé e wá fún un kó lè jẹ ẹ́, Ámínónì rá a mú, ó sì sọ pé: “Wá sùn tì mí, àbúrò mi.” 12 Àmọ́, ó sọ fún un pé: “Rárá o, ẹ̀gbọ́n mi! Má ṣe kó ẹ̀gàn bá mi, nítorí ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Ísírẹ́lì.+ Má ṣe ohun tó ń dójú tini yìí.+
-