-
Léfítíkù 7:34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Torí mo mú igẹ̀ ọrẹ fífì àti ẹsẹ̀ ìpín mímọ́ náà látinú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo sì fún àlùfáà Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kó jẹ́ ìlànà tó máa wà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ títí lọ.
-
-
Diutarónómì 18:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Kí o fún un ní àkọ́so ọkà rẹ, wáìnì tuntun rẹ, òróró rẹ àti irun tí o bá kọ́kọ́ rẹ́ lára agbo ẹran rẹ.+
-
-
1 Kọ́ríńtì 9:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé àwọn ọkùnrin tó ń ṣe iṣẹ́ mímọ́ máa ń jẹ àwọn nǹkan tẹ́ńpìlì àti pé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nídìí pẹpẹ máa ń gba ìpín nídìí pẹpẹ?+
-