ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 23:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 “Kí o mú èyí tó dáa jù nínú àwọn èso tó kọ́kọ́ pọ́n ní ilẹ̀ rẹ wá sí ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+

      “O ò gbọ́dọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.+

  • Nọ́ńbà 18:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Jèhófà tún sọ fún Áárónì pé: “Èmi fúnra mi fi gbogbo ọrẹ tí wọ́n bá ṣe fún mi+ sí ìkáwọ́ rẹ. Mo ti fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lára gbogbo ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fi ṣe ọrẹ, kó jẹ́ ìpín+ yín títí lọ.

  • Nọ́ńbà 18:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “Mo fún ọ+ ní gbogbo òróró tó dáa jù àti gbogbo wáìnì tuntun tó dáa jù àti ọkà, àkọ́so+ wọn, èyí tí wọ́n fún Jèhófà.

  • 2 Kíróníkà 31:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Yàtọ̀ síyẹn, ó pàṣẹ fún àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù pé kí wọ́n fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ní apá tó tọ́ sí wọn,+ kí wọ́n lè gbájú mọ́ òfin Jèhófà.*

  • Nehemáyà 12:44
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 44 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n yan àwọn tí á máa bójú tó àwọn ilé ìkẹ́rùsí,+ èyí tó wà fún àwọn ọrẹ,+ àwọn àkọ́so èso+ àti àwọn ìdá mẹ́wàá.+ Inú àwọn ilé náà ni wọ́n á máa kó àwọn nǹkan tí wọ́n kórè látinú àwọn oko tó wà ní àwọn ìlú sí, gẹ́gẹ́ bí Òfin ṣe sọ+ pé kí wọ́n máa fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì.+ Àwọn èèyàn sì ń yọ̀ ní Júdà torí pé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́