2 Rúùtù ará Móábù sọ fún Náómì pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ sí oko, kí n lè pèéṣẹ́+ lára ṣírí ọkà lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni tó bá ṣojúure sí mi.” Torí náà, Náómì sọ fún un pé: “Lọ, ọmọ mi.” 3 Lẹ́yìn náà, ó lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pèéṣẹ́ lẹ́yìn àwọn olùkórè. Láìmọ̀, ó dé oko Bóásì+ tó wá láti ìdílé Élímélékì.+