ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 15:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 “Tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ bá di aláìní láàárín rẹ nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, o ò gbọ́dọ̀ mú kí ọkàn rẹ le tàbí kí o háwọ́ sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní.+

  • Diutarónómì 15:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Kí o lawọ́ sí i dáadáa,+ kí o* má sì ráhùn tí o bá ń fún un, torí èyí á mú kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe àtàwọn ohun tí o bá dáwọ́ lé.+

  • Òwe 11:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Ẹnì kan wà tó ń fúnni lọ́pọ̀lọpọ̀,* ó sì ń ní sí i;+

      Ẹnì kan sì wà tó ń fawọ́ ohun tó yẹ kó fúnni sẹ́yìn, àmọ́ ó di aláìní.+

  • Òwe 19:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan,+

      Á sì san án* pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.+

  • Lúùkù 6:38
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 38 Ẹ sọ ọ́ di àṣà láti máa fúnni, àwọn èèyàn sì máa fún yín.+ Wọ́n máa da òṣùwọ̀n tó dáa, tí a kì mọ́lẹ̀, tí a mì pọ̀, tó sì kún àkúnwọ́sílẹ̀, sórí itan yín. Torí òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni la máa fi díwọ̀n pa dà fún yín.”

  • 2 Kọ́ríńtì 9:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Àmọ́ ní ti èyí, ẹni tó bá ń fúnrúgbìn díẹ̀ máa kórè díẹ̀, ẹni tó bá sì ń fúnrúgbìn yanturu máa kórè yanturu.+

  • 1 Jòhánù 3:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ní ohun ìní ayé yìí, tó sì rí i pé arákùnrin rẹ̀ ṣaláìní síbẹ̀ tí kò ṣàánú rẹ̀, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe wà nínú rẹ̀?+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́