-
Ẹ́kísódù 27:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 “Kí o pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n gbé ògidì òróró ólífì tí wọ́n fún wá sọ́dọ̀ rẹ láti máa fi tan iná, kí àwọn fìtílà náà lè máa wà ní títàn nígbà gbogbo.+ 21 Nínú àgọ́ ìpàdé, lẹ́yìn òde aṣọ ìdábùú tó wà nítòsí Ẹ̀rí náà,+ kí Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ ṣètò bí àwọn fìtílà náà á ṣe máa wà ní títàn láti alẹ́ títí di àárọ̀ níwájú Jèhófà.+ Àṣẹ yìí ni kí gbogbo ìran wọn máa tẹ̀ lé títí lọ, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe é.+
-
-
Nọ́ńbà 8:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Sọ fún Áárónì pé, ‘Tí o bá tan àwọn fìtílà, kí fìtílà méje mọ́lẹ̀ síwájú ọ̀pá fìtílà+ náà.’”
-