35 Ó tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, màá yin Jèhófà.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Júdà.*+ Lẹ́yìn ìyẹn, kò bímọ mọ́.
3 “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Júdà pàgọ́ sí ìlà oòrùn, lápá ibi tí oòrùn ti ń yọ, ní àwùjọ-àwùjọ;* Náṣónì+ ọmọ Ámínádábù ni ìjòyè àwọn ọmọ Júdà. 4 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (74,600).+