29 Nígbà tó wòkè, tó sì rí Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀, ọmọ ìyá+ rẹ̀, ó bi wọ́n pé: “Ṣé àbúrò yín tó kéré jù tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi nìyí?”+ Ó sọ pé: “Kí Ọlọ́run ṣojúure sí ọ, ọmọ mi.”
22 Kí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì wá tẹ̀ lé wọn; Ábídánì+ ọmọ Gídéónì ni ìjòyè àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì. 23 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (35,400).+