-
Léfítíkù 27:30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 “‘Gbogbo ìdá mẹ́wàá+ ilẹ̀ náà jẹ́ ti Jèhófà, ì báà jẹ́ látinú irè oko ilẹ̀ náà tàbí èso igi. Ohun mímọ́ fún Jèhófà ni.
-
-
Nehemáyà 10:37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
37 Bákan náà, a ó máa mú àkọ́so ọkà tí a kò lọ̀ kúnná+ wá àti àwọn ọrẹ pẹ̀lú èso oríṣiríṣi igi+ àti wáìnì tuntun pẹ̀lú òróró,+ a ó sì kó wọn wá fún àwọn àlùfáà ní àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* ní ilé Ọlọ́run wa,+ a ó sì kó ìdá mẹ́wàá irè oko ilẹ̀ wa fún àwọn ọmọ Léfì,+ torí àwọn ni wọ́n ń gba ìdá mẹ́wàá ní gbogbo ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀.
-
-
Nehemáyà 12:44Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
44 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n yan àwọn tí á máa bójú tó àwọn ilé ìkẹ́rùsí,+ èyí tó wà fún àwọn ọrẹ,+ àwọn àkọ́so èso+ àti àwọn ìdá mẹ́wàá.+ Inú àwọn ilé náà ni wọ́n á máa kó àwọn nǹkan tí wọ́n kórè látinú àwọn oko tó wà ní àwọn ìlú sí, gẹ́gẹ́ bí Òfin ṣe sọ+ pé kí wọ́n máa fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì.+ Àwọn èèyàn sì ń yọ̀ ní Júdà torí pé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn.
-