6 “Jẹ́ kí ẹ̀yà Léfì+ wá síwájú, kí o sì ní kí wọ́n dúró níwájú àlùfáà Áárónì, kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́+ fún un. 7 Kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ wọn ní àgọ́ ìjọsìn, èyí ni ojúṣe wọn fún un àti fún gbogbo àpéjọ náà níwájú àgọ́ ìpàdé.
18Jèhófà wá sọ fún Áárónì pé: “Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti agbo ilé bàbá rẹ pẹ̀lú rẹ ni yóò máa dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí lòdì sí ibi mímọ́,+ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ ni yóò sì máa dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí lòdì sí iṣẹ́ àlùfáà+ yín.