21 Ísírẹ́lì wá ní kí àwọn ìránṣẹ́ lọ bá Síhónì ọba àwọn Ámórì pé:+22 “Jẹ́ ká gba ilẹ̀ rẹ kọjá. A ò ní yà sínú oko tàbí sínú ọgbà àjàrà. A ò ní mu omi inú kànga kankan. Ojú Ọ̀nà Ọba la máa gbà títí a fi máa kọjá ní ilẹ̀+ rẹ.”
26 “Mo wá ní kí àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù Kédémótì+ lọ jíṣẹ́ àlàáfíà+ yìí fún Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì pé, 27 ‘Jẹ́ kí n gba ilẹ̀ rẹ kọjá. Mi ò ní kọjá ojú ọ̀nà, mi ò sì ní yà sí ọ̀tún tàbí òsì.+