-
Nọ́ńbà 22:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ó ní kí àwọn ìránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Báláámù ọmọ Béórì ní Pétórì,+ èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Odò* ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀. Ó sọ pé kí wọ́n pè é wá, ó ní: “Wò ó! Àwọn èèyàn kan ti wá láti Íjíbítì. Wò ó! Wọ́n bo ilẹ̀,*+ iwájú mi gan-an ni wọ́n sì ń gbé. 6 Torí náà, jọ̀ọ́ wá bá mi gégùn-ún+ fún àwọn èèyàn yìí, torí wọ́n lágbára jù mí lọ. Bóyá màá lè ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ náà, torí ó dá mi lójú pé ẹni tí o bá súre fún máa rí ìbùkún gbà, ègún sì máa wà lórí ẹni tí o bá gégùn-ún fún.”
-
-
Nọ́ńbà 23:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Bálákì wá sọ fún Báláámù pé: “Kí lo ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá kí o lè gégùn-ún fún àwọn ọ̀tá mi, àmọ́ ṣe lo kàn wá ń súre fún wọn.”+
-
-
Nọ́ńbà 24:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Inú wá bí Bálákì sí Báláámù gan-an. Bálákì wá fi ìbínú pàtẹ́wọ́, ó sì sọ fún Báláámù pé: “Torí kí o lè gégùn-ún fún àwọn ọ̀tá mi ni mo ṣe pè ọ́ + wá, àmọ́ ṣe lo kàn ń súre fún wọn lẹ́ẹ̀mẹta yìí.
-