-
Diutarónómì 8:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Tí o bá ti jẹun, tí o sì ti yó, tí o ti kọ́ àwọn ilé tó rẹwà, tí o sì ń gbé níbẹ̀,+ 13 tí ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti agbo ẹran rẹ di púpọ̀, tí fàdákà àti wúrà rẹ pọ̀ sí i, tí gbogbo ohun ìní rẹ sì pọ̀ rẹpẹtẹ, 14 má ṣe gbéra ga nínú ọkàn rẹ,+ kó sì mú kí o gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú,+
-
-
Diutarónómì 29:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè pé kó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá ní ilẹ̀ Móábù, yàtọ̀ sí májẹ̀mú tó bá wọn dá ní Hórébù.+
-