12 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè àti Áárónì pé: “Torí pé ẹ ò fi hàn pé ẹ gbà mí gbọ́, ẹ ò sì fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ ò ní mú ìjọ yìí dé ilẹ̀ tí màá fún wọn.”+ 13 Èyí ni omi Mẹ́ríbà,+ ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti bá Jèhófà jà, tó sì fi hàn wọ́n pé mímọ́ ni òun.