-
Nọ́ńbà 27:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Gun orí òkè Ábárímù+ yìí, kí o sì wo ilẹ̀ tí màá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 13 Tí o bá ti rí i, a máa kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ,*+ bíi ti Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ,+ 14 torí nígbà tí àpéjọ náà ń bá mi jà ní aginjù Síínì, ẹ ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ tí mo pa pé kí ẹ tipasẹ̀ omi+ náà fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ níṣojú wọn. Èyí ni omi Mẹ́ríbà+ tó wà ní Kádéṣì + ní aginjù Síínì.”+
-
-
Diutarónómì 1:37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
37 (Torí yín ni Jèhófà tiẹ̀ ṣe bínú sí mi, ó ní, “Ìwọ náà ò ní wọ ibẹ̀.+
-
-
Diutarónómì 3:26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Àmọ́ Jèhófà ṣì ń bínú sí mi gidigidi nítorí yín,+ kò sì dá mi lóhùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Ó tó gẹ́ẹ́! O ò gbọ́dọ̀ bá mi sọ̀rọ̀ yìí mọ́.
-