12 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè àti Áárónì pé: “Torí pé ẹ ò fi hàn pé ẹ gbà mí gbọ́, ẹ ò sì fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ ò ní mú ìjọ yìí dé ilẹ̀ tí màá fún wọn.”+
31Lẹ́yìn náà, Mósè jáde lọ sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo Ísírẹ́lì, 2 ó sọ fún wọn pé: “Ẹni ọgọ́fà (120) ọdún ni mí lónìí.+ Mi ò lè darí yín mọ́,* torí Jèhófà ti sọ fún mi pé, ‘O ò ní sọdá Jọ́dánì yìí.’+