-
Diutarónómì 12:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Gbogbo ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ máa lé kúrò bá ti sin àwọn ọlọ́run wọn ni kí ẹ pa run pátápátá,+ ì báà jẹ́ lórí àwọn òkè tó ga tàbí lórí àwọn òkè kéékèèké tàbí lábẹ́ igi èyíkéyìí tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. 3 Kí ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, kí ẹ fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn túútúú,+ kí ẹ dáná sun àwọn òpó òrìṣà* wọn, kí ẹ sì gé ère àwọn ọlọ́run wọn+ tí wọ́n gbẹ́ lulẹ̀, kí orúkọ wọn lè pa rẹ́ kúrò níbẹ̀.+
-