31 “Màá pààlà fún yín láti Òkun Pupa dé òkun àwọn Filísínì àti láti aginjù dé Odò;*+ torí màá mú kí ọwọ́ yín tẹ àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà, ẹ ó sì lé wọn kúrò níwájú yín.+
23 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ títí o fi máa ṣẹ́gun wọn tí o sì máa pa wọ́n run pátápátá.+24 Ó máa fi àwọn ọba wọn lé ọ lọ́wọ́,+ o sì máa pa orúkọ wọn run kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ Kò sẹ́ni tó máa dìde sí ọ+ títí o fi máa pa wọ́n run tán.+