ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 30:1-3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 “Tí gbogbo ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹ sí ọ lára, ìbùkún àti ègún tí mo fi síwájú rẹ,+ tí o sì rántí wọn*+ ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí, 2 tí o wá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, tí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara*+ rẹ fetí sí ohùn rẹ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, 3 nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n kó lẹ́rú+ pa dà wá, ó máa ṣàánú+ rẹ, ó sì máa kó ọ jọ látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí.

  • Diutarónómì 30:8-10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 “Nígbà náà, wàá pa dà, wàá fetí sí ohùn Jèhófà, wàá sì pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mò ń pa fún ọ lónìí mọ́. 9 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́+ rẹ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó máa mú kí àwọn ọmọ rẹ, àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ di púpọ̀, torí pé lẹ́ẹ̀kan sí i inú Jèhófà máa dùn láti mú kí nǹkan lọ dáadáa fún ọ bí inú rẹ̀ ṣe dùn sí àwọn baba ńlá+ rẹ. 10 Nígbà yẹn, wàá fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ, wàá sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn òfin rẹ̀ tí wọ́n kọ sínú ìwé Òfin yìí, wàá sì fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara*+ rẹ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.

  • 1 Àwọn Ọba 8:48, 49
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 48 tí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn+ àti gbogbo ara* wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá tó kó wọn lọ sóko ẹrú, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ ní ìdojúkọ ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn àti ìlú tí o yàn àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,+ 49 nígbà náà, láti ibi tí ò ń gbé ní ọ̀run,+ kí o gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn pé kí o ṣojú rere sí àwọn, kí o sì ṣe ìdájọ́ nítorí wọn,

  • Jeremáyà 29:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 “‘Ẹ ó wá mi, ẹ ó sì rí mi,+ nítorí gbogbo ọkàn yín ni ẹ ó fi wá mi.+

  • Jóẹ́lì 2:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “Síbẹ̀, ẹ fi gbogbo ọkàn yín pa dà sọ́dọ̀ mi báyìí,” ni Jèhófà wí,+

      “Kí ẹ gbààwẹ̀,+ kí ẹ sunkún, kí ẹ sì pohùn réré ẹkún.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́