-
Nọ́ńbà 18:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 “Wò ó, mo ti fún àwọn ọmọ Léfì ní gbogbo ìdá mẹ́wàá+ ní Ísírẹ́lì, kó jẹ́ ogún wọn torí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé.
-
-
Nehemáyà 10:38, 39Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
38 Kí àlùfáà, ọmọ Áárónì, wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nígbà tí àwọn ọmọ Léfì bá ń gba ìdá mẹ́wàá; kí àwọn ọmọ Léfì mú ìdá mẹ́wàá lára ìdá mẹ́wàá ti ilé Ọlọ́run wa,+ kí wọ́n sì kó o sí àwọn yàrá* tó wà ní ilé ìkẹ́rùsí. 39 Inú àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Léfì máa mú ọrẹ+ ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá,+ ibẹ̀ sì ni kí àwọn nǹkan èlò ibi mímọ́ máa wà títí kan àwọn àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn àti àwọn aṣọ́bodè pẹ̀lú àwọn akọrin. A kò sì ní pa ilé Ọlọ́run wa tì.+
-
-
Málákì 3:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “Ṣé èèyàn lásán lè ja Ọlọ́run lólè? Àmọ́ ẹ̀ ń jà mí lólè.”
Ẹ sì sọ pé: “Ọ̀nà wo ni a gbà jà ọ́ lólè?”
“Nínú ìdá mẹ́wàá àti ọrẹ ni.
-