Diutarónómì 24:19 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 19 “Tí o bá kórè oko rẹ, tí o sì gbàgbé ìtí ọkà kan sínú oko, o ò gbọ́dọ̀ pa dà lọ gbé e. Fi sílẹ̀ níbẹ̀ fún àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.+ Sáàmù 41:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 41 Aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń ro ti àwọn aláìní;+Jèhófà yóò gbà á sílẹ̀ ní ọjọ́ àjálù.
19 “Tí o bá kórè oko rẹ, tí o sì gbàgbé ìtí ọkà kan sínú oko, o ò gbọ́dọ̀ pa dà lọ gbé e. Fi sílẹ̀ níbẹ̀ fún àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.+