Ẹ́kísódù 20:12 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 12 “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,+ kí ẹ̀mí rẹ lè gùn lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.+ Diutarónómì 27:16 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 16 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá fojú kéré bàbá àti ìyá rẹ̀.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’) Òwe 1:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Ọmọ mi, fetí sí ìbáwí bàbá rẹ,+Má sì pa ẹ̀kọ́* ìyá rẹ tì.+ Éfésù 6:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu+ nínú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo.