ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 20:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,+ kí ẹ̀mí rẹ lè gùn lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.+

  • Diutarónómì 21:18-21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 “Tí ọkùnrin kan bá ní ọmọ kan tó jẹ́ alágídí àti ọlọ̀tẹ̀, tí kì í gbọ́ràn sí bàbá àti ìyá rẹ̀ lẹ́nu,+ tí wọ́n sì ti gbìyànjú títí láti tọ́ ọ sọ́nà, àmọ́ tó kọ̀ tí ò gbọ́ tiwọn,+ 19 kí bàbá àti ìyá rẹ̀ mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn àgbààgbà ní ẹnubodè ìlú rẹ̀, 20 kí wọ́n sì sọ fún àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ pé, ‘Alágídí àti ọlọ̀tẹ̀ ni ọmọ wa yìí, kì í gbọ́ tiwa. Alájẹkì+ àti ọ̀mùtípara+ sì ni.’ 21 Kí gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa. Kí o mú ohun tó burú kúrò láàárín rẹ, tí gbogbo Ísírẹ́lì bá sì gbọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n.+

  • Òwe 20:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Ẹni tó bá bú bàbá àti ìyá rẹ̀,

      Fìtílà rẹ̀ yóò kú nígbà tí òkùnkùn bá ṣú.+

  • Òwe 30:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Ojú tó ń fi bàbá ṣẹ̀sín, tí kì í sì í ṣègbọràn sí ìyá,+

      Àwọn ẹyẹ ìwò tó wà ní àfonífojì yóò yọ ọ́ jáde,

      Àwọn ọmọ ẹyẹ idì yóò sì mú un jẹ.+

  • Mátíù 15:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ pé, ‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ’+ àti pé, ‘Kí ẹ pa ẹni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí* bàbá tàbí ìyá rẹ̀.’+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́