7 “Ṣáà rí i pé o jẹ́ onígboyà àti alágbára gidigidi, kí o sì rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo Òfin tí Mósè ìránṣẹ́ mi pa láṣẹ fún ọ. Má yà kúrò nínú rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+ kí o lè máa hùwà ọgbọ́n níbikíbi tí o bá lọ.+
21 Etí rẹ sì máa gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ pé, “Èyí ni ọ̀nà.+ Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,” tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yà sí apá ọ̀tún tàbí tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yà sí apá òsì.+