-
Nọ́ńbà 32:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Mósè dá wọn lóhùn pé: “Tí ẹ bá lè ṣe èyí: Kí ẹ gbé ohun ìjà yín níwájú Jèhófà láti jagun+ náà; 21 tí gbogbo yín bá sì gbé ohun ìjà, tí ẹ sọdá Jọ́dánì níwájú Jèhófà nígbà tó ń lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ kúrò níwájú rẹ̀,+ 22 títí a fi máa gba ilẹ̀ náà níwájú Jèhófà,+ nígbà náà, ẹ lè pa dà,+ ẹ ò sì ní jẹ̀bi lọ́dọ̀ Jèhófà àti Ísírẹ́lì. Ilẹ̀ yìí á wá di tiyín níwájú Jèhófà.+
-
-
Jóṣúà 22:1-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Jóṣúà wá ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, 2 ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ti ṣe gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ fún yín,+ ẹ sì ti tẹ̀ lé gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín.+ 3 Ẹ ò pa àwọn arákùnrin yín tì ní gbogbo àsìkò yìí, títí dòní;+ ẹ sì ń ṣe àwọn ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ.+ 4 Jèhófà Ọlọ́run yín ti wá fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi, bó ṣe ṣèlérí fún wọn.+ Torí náà, ẹ lè pa dà sí àgọ́ yín ní ilẹ̀ tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà fún yín pé kí ẹ jogún ní òdìkejì* Jọ́dánì.+
-