14 “Ẹ wò ó! Mi ò ní pẹ́ kú,* ẹ sì mọ̀ dáadáa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín pé kò sí ìkankan nínú gbogbo ìlérí tó dáa tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe fún yín tí kò ṣẹ. Gbogbo wọn ló ṣẹ fún yín. Ìkankan nínú wọn ò kùnà.+
56 “Ìyìn ni fún Jèhófà, tí ó fún àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì ní ibi ìsinmi bí ó ti ṣèlérí.+ Kò sí ìkankan nínú gbogbo ìlérí tí ó ṣe nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó lọ láìṣẹ.+
18 kó lè jẹ́ pé nípasẹ̀ àwọn nǹkan méjì tí kò lè yí pa dà, tí Ọlọ́run ò ti lè parọ́,+ àwa tí a ti sá sí ibi ààbò máa lè rí ìṣírí tó lágbára gbà láti di ìrètí tó wà níwájú wa mú ṣinṣin.