12 Ó fèsì pé: “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ,+ ohun tí yóò sì jẹ́ àmì fún ọ pé èmi ni mo rán ọ nìyí: Lẹ́yìn tí o bá ti mú àwọn èèyàn náà kúrò ní Íjíbítì, ẹ máa jọ́sìn* Ọlọ́run tòótọ́ lórí òkè yìí.”+
7 Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: “Òní yìí ni mo máa bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga níṣojú gbogbo Ísírẹ́lì,+ kí wọ́n lè mọ̀ pé màá wà pẹ̀lú rẹ+ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mósè.+