-
Jẹ́nẹ́sísì 15:18-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà bá Ábúrámù dá májẹ̀mú+ kan pé: “Ọmọ* rẹ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí,+ láti odò Íjíbítì dé odò ńlá náà, ìyẹn odò Yúfírétì:+ 19 ilẹ̀ àwọn Kénì,+ àwọn ọmọ Kénásì, àwọn Kádímónì, 20 àwọn ọmọ Hétì,+ àwọn Pérísì,+ àwọn Réfáímù,+ 21 àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Gẹ́gáṣì àti àwọn ará Jébúsì.”+
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 3:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ń gbé láàárín àwọn ọmọ Kénáánì,+ àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.
-
-
1 Àwọn Ọba 9:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ní ti gbogbo èèyàn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ tí wọn kì í ṣe ara àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,+ 21 àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà, ìyẹn àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè pa run, Sólómọ́nì ní kí wọ́n máa ṣíṣẹ́ fún òun bí ẹrú títí di òní yìí.+
-