-
Ẹ́kísódù 33:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: “Kúrò níbí pẹ̀lú àwọn èèyàn tí o mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Kí ẹ lọ sí ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù pé, ‘Ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ ni màá fún.’+ 2 Màá rán áńgẹ́lì kan ṣáájú yín,+ màá sì lé àwọn ọmọ Kénáánì kúrò, pẹ̀lú àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+
-
-
Diutarónómì 7:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tí o fẹ́ wọ̀ tí o sì máa gbà,+ ó máa mú àwọn orílẹ̀-èdè tí èèyàn wọn pọ̀ kúrò níwájú rẹ:+ àwọn ọmọ Hétì, àwọn Gẹ́gáṣì, àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ àwọn orílẹ̀-èdè méje tí èèyàn wọn pọ̀ tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ.+
-
-
Nehemáyà 9:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, tó yan Ábúrámù,+ tó mú un jáde kúrò ní Úrì,+ ìlú àwọn ará Kálídíà, tó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ábúráhámù.+ 8 O rí i pé ó jẹ́ olóòótọ́ níwájú rẹ,+ torí náà, o bá a dá májẹ̀mú láti fún un ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn ará Jébúsì àti àwọn Gẹ́gáṣì, pé kó fún àwọn ọmọ* rẹ̀;+ o sì mú ìlérí rẹ ṣẹ nítorí pé olódodo ni ọ́.
-