ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 11:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Torí náà, gbogbo àwọn èèyàn náà lọ sí Gílígálì, wọ́n sì fi Sọ́ọ̀lù jẹ ọba níwájú Jèhófà ní Gílígálì. Wọ́n rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níbẹ̀ níwájú Jèhófà,+ Sọ́ọ̀lù àti gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì sì ṣe ayẹyẹ pẹ̀lú ìdùnnú ńlá.+

  • 1 Sámúẹ́lì 13:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ni Sámúẹ́lì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ìwà òmùgọ̀ lo hù. O ò ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ pa fún ọ.+ Ká ní o ṣe bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ì bá fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì títí láé.

  • 1 Sámúẹ́lì 15:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 Àmọ́ Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Mi ò ní bá ọ pa dà, nítorí o ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, Jèhófà sì ti kọ̀ ọ́ pé kí o má ṣe jẹ́ ọba lórí Ísírẹ́lì mọ́.”+

  • 1 Sámúẹ́lì 28:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó jẹ́ abẹ́mìílò,+ màá lọ wádìí lọ́wọ́ rẹ̀.” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Wò ó! Obìnrin kan tí ó jẹ́ abẹ́mìílò wà ní Ẹ́ń-dórì.”+

  • 1 Sámúẹ́lì 31:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pé: “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi ní àgúnyọ, kí àwọn aláìdádọ̀dọ́*+ yìí má bàa wá gún mi ní àgúnyọ, kí wọ́n sì hùwà ìkà sí mi.”* Àmọ́, ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ẹ̀rù bà á gan-an. Torí náà, Sọ́ọ̀lù mú idà, ó sì ṣubú lé e.+

  • 2 Sámúẹ́lì 1:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì,+ àwọn ẹni ọ̀wọ́n àti àyànfẹ́* nígbà ayé wọn,

      A kò sì pín wọn níyà nígbà ikú wọn.+

      Wọ́n yára ju ẹyẹ idì lọ,+

      Wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́