-
1 Sámúẹ́lì 10:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ṣé ẹ rí ẹni tí Jèhófà yàn,+ pé kò sí ẹnì kankan tó dà bíi rẹ̀ láàárín gbogbo èèyàn?” Gbogbo àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “Kí ẹ̀mí ọba ó gùn o!”
-
-
1 Sámúẹ́lì 11:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ wá kí a lọ sí Gílígálì+ láti fìdí ipò ọba náà múlẹ̀.”+ 15 Torí náà, gbogbo àwọn èèyàn náà lọ sí Gílígálì, wọ́n sì fi Sọ́ọ̀lù jẹ ọba níwájú Jèhófà ní Gílígálì. Wọ́n rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níbẹ̀ níwájú Jèhófà,+ Sọ́ọ̀lù àti gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì sì ṣe ayẹyẹ pẹ̀lú ìdùnnú ńlá.+
-