9“Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, ò ń sọdá Jọ́dánì lónìí,+ láti wọ ilẹ̀ náà kí o lè lọ lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ kúrò,+ àwọn ìlú tó tóbi, tí wọ́n sì mọ odi rẹ̀ kan ọ̀run,*+
3 Torí náà, kí o mọ̀ lónìí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa sọdá ṣáájú rẹ.+ Ó jẹ́ iná tó ń jóni run,+ ó sì máa pa wọ́n run. Ó máa tẹ̀ wọ́n lórí ba níṣojú yín kí ẹ lè tètè lé wọn jáde,* kí ẹ sì pa wọ́n run, bí Jèhófà ṣe ṣèlérí fún ọ.+