19 Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ti mú kí o sinmi lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá rẹ tó yí ọ ká, ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún,+ kí o pa orúkọ Ámálékì rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ O ò gbọ́dọ̀ gbàgbé.
3 Ní báyìí, lọ ṣá àwọn ọmọ Ámálékì+ balẹ̀, kí o sì pa wọ́n run pátápátá+ pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní. O ò gbọ́dọ̀ dá wọn sí;* ṣe ni kí o pa gbogbo wọn,+ ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti ọmọ jòjòló, akọ màlúù àti àgùntàn, ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’”+