22 Élì ti darúgbó gan-an, àmọ́ ó ti gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe+ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti bí wọ́n ṣe ń bá àwọn obìnrin tó ń sìn ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé sùn.+ 23 Ó sì máa ń sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan yìí? Ohun tí mò ń gbọ́ nípa yín látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn kò dáa.