11 Ó ní: “Ohun tí ọba tó bá jẹ lórí yín máa lẹ́tọ̀ọ́ láti gbà nìyí:+ Á mú àwọn ọmọkùnrin yín,+ á sì fi wọ́n sínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀,+ á wá sọ wọ́n di agẹṣin rẹ̀,+ àwọn kan á sì ní láti máa sáré níwájú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀.
5 Ní àkókò yìí, Ádóníjà+ ọmọkùnrin Hágítì ń gbé ara rẹ̀ ga, ó ń sọ pé: “Èmi ló máa di ọba!” Ó ní kí wọ́n ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún òun, ó kó àwọn agẹṣin jọ àti àádọ́ta (50) ọkùnrin tí á máa sáré níwájú rẹ̀.+