-
1 Sámúẹ́lì 24:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ó sọ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: “Jèhófà ò ní fẹ́ gbọ́ rárá pé mo ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí olúwa mi, ẹni àmì òróró Jèhófà, pé mo gbé ọwọ́ mi sókè sí i, torí ẹni àmì òróró Jèhófà ni.”+ 7 Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yìí ló fi dá àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dúró,* kò sì gbà wọ́n láyè láti kọ lu Sọ́ọ̀lù. Àmọ́, Sọ́ọ̀lù dìde, ó kúrò nínú ihò náà, ó sì bá tiẹ̀ lọ.
-
-
1 Sámúẹ́lì 26:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Jèhófà ò ní fẹ́ gbọ́ rárá pé mo gbé ọwọ́ mi sókè sí ẹni àmì òróró Jèhófà!+ Ní báyìí, jọ̀wọ́ jẹ́ ká mú ọ̀kọ̀ àti ìgò omi tó wà níbi orí rẹ̀, kí a sì máa bá tiwa lọ.”
-
-
Sáàmù 3:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Jèhófà, kí nìdí tí àwọn ọ̀tá mi fi pọ̀ tó báyìí?+
Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń dìde sí mi?+
-