-
1 Àwọn Ọba 2:31, 32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Ni ọba bá sọ fún un pé: “Ohun tí ó sọ ni kí o ṣe; ṣá a balẹ̀, kí o sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ tí Jóábù ta sílẹ̀ láìyẹ+ kúrò lórí mi àti kúrò lórí ilé bàbá mi. 32 Jèhófà yóò mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sórí rẹ̀, nítorí ó fi idà ṣá àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n lóòótọ́ jù ú lọ balẹ̀, tí wọ́n sì dára jù ú, ó pa wọ́n láìjẹ́ kí Dáfídì bàbá mi mọ̀. Àwọn ọkùnrin náà ni: Ábínérì+ ọmọ Nérì, olórí ọmọ ogun Ísírẹ́lì+ àti Ámásà+ ọmọ Jétà, olórí ọmọ ogun Júdà.+
-