ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 9:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Ẹnikẹ́ni tó bá ta ẹ̀jẹ̀ èèyàn sílẹ̀, èèyàn ni yóò ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀,+ torí àwòrán Ọlọ́run ni Ó dá èèyàn.+

  • Ẹ́kísódù 21:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Tí ẹnì kan bá bínú gidigidi sí ọmọnìkejì rẹ̀, tó sì mọ̀ọ́mọ̀ pa á,+ kí ẹ pa onítọ̀hún, ì báà jẹ́ ibi pẹpẹ mi lo ti máa wá mú un.+

  • Nọ́ńbà 35:33
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 “‘Ẹ má sọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé di ẹlẹ́gbin, torí ẹ̀jẹ̀ máa ń sọ ilẹ̀+ di ẹlẹ́gbin, kò sì sí ètùtù fún ẹ̀jẹ̀ tí ẹnì kan ta sórí ilẹ̀ àyàfi ẹ̀jẹ̀ ẹni náà tó ta á sílẹ̀.+

  • Diutarónómì 19:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 O* ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀, ṣe ni kí o mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ kúrò ní Ísírẹ́lì,+ kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ.

  • 1 Àwọn Ọba 2:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 “Ìwọ náà mọ ohun tí Jóábù ọmọ Seruáyà ṣe sí mi dáadáa, ohun tó ṣe sí àwọn olórí ọmọ ogun Ísírẹ́lì méjì, ìyẹn Ábínérì+ ọmọ Nérì àti Ámásà+ ọmọ Jétà. Ó pa wọ́n nígbà tí kì í ṣe pé ogun ń jà, ó mú kí ẹ̀jẹ̀+ ogun ta sára àmùrè tó sán mọ́ ìbàdí rẹ̀ àti sára bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́