-
Diutarónómì 12:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Kàkà bẹ́ẹ̀, ibikíbi tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ wà àti ibi tó bá ń gbé láàárín gbogbo ẹ̀yà yín ni kí ẹ ti máa wá a, ibẹ̀ sì ni kí ẹ máa lọ.+ 6 Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú àwọn ẹbọ sísun yín wá+ àti àwọn ẹbọ yín, àwọn ìdá mẹ́wàá yín,+ ọrẹ látọwọ́ yín,+ àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, àwọn ọrẹ àtinúwá+ yín àti àwọn àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran yín.+
-
-
1 Àwọn Ọba 5:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 “O mọ̀ dáadáa pé Dáfídì bàbá mi kò lè kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ nítorí ogun tí wọ́n fi yí i ká, títí Jèhófà fi fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.+
-
-
1 Kíróníkà 28:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 “Ó sọ fún mi pé, ‘Sólómọ́nì ọmọ rẹ ló máa kọ́ ilé mi àti àwọn àgbàlá mi, nítorí mo ti yàn án ṣe ọmọ mi, màá sì di bàbá rẹ̀.+
-