-
2 Kíróníkà 1:3-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Nígbà náà, Sólómọ́nì àti gbogbo ìjọ náà lọ sí ibi gíga tó wà ní Gíbíónì,+ torí pé ibẹ̀ ni àgọ́ ìpàdé Ọlọ́run tòótọ́ wà, èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa ní aginjù. 4 Àmọ́, Dáfídì ti gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá láti Kiriati-jéárímù+ sí ibi tí Dáfídì ṣètò sílẹ̀ fún un; ó ti pa àgọ́ fún un ní Jerúsálẹ́mù.+ 5 Wọ́n ti gbé pẹpẹ bàbà+ tí Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọ Úráì ọmọ Húrì ṣe sí iwájú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà; Sólómọ́nì àti gbogbo ìjọ sì máa ń gbàdúrà níwájú rẹ̀.* 6 Sólómọ́nì wá rú àwọn ẹbọ níbẹ̀ níwájú Jèhófà, ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹran ẹbọ sísun ló sì fi rúbọ lórí pẹpẹ bàbà+ tó wà ní àgọ́ ìpàdé.
-