2 “Wò ó, mo ti yan Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọ Úráì ọmọ Húrì látinú ẹ̀yà Júdà.+ 3 Màá fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún inú rẹ̀, màá fún un ní ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ nípa onírúurú iṣẹ́ ọnà, 4 kó lè ṣe iṣẹ́ ọnà ayàwòrán, kó lè fi wúrà, fàdákà àti bàbà ṣiṣẹ́, 5 kó lè gé òkúta, kó sì tò ó,+ kó sì lè fi igi ṣe onírúurú nǹkan.+