-
1 Àwọn Ọba 8:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Jèhófà ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, torí mo ti jọba ní ipò Dáfídì bàbá mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, bí Jèhófà ti ṣèlérí. Mo tún kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+
-
-
1 Kíróníkà 17:11-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 “‘“Nígbà tí o bá kú, tí o sì lọ síbi tí àwọn baba ńlá rẹ wà, màá gbé ọmọ* rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ,+ màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.+ 12 Òun ló máa kọ́ ilé fún mi,+ màá sì fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.+ 13 Màá di bàbá rẹ̀, á sì di ọmọ mi.+ Mi ò ní mú ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kúrò lára rẹ̀+ bí mo ṣe mú un kúrò lára ẹni tó ṣáájú rẹ.+ 14 Màá mú kó dúró nínú ilé mi àti nínú ìjọba mi títí láé,+ ìtẹ́ rẹ̀ á sì wà títí láé.”’”+
-
-
Sáàmù 132:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Jèhófà ti búra fún Dáfídì,
Ó dájú pé kò ní ṣàìmú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ pé:
-
-
Mátíù 22:42Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
42 “Kí lèrò yín nípa Kristi? Ọmọ ta ni?” Wọ́n sọ fún un pé: “Ọmọ Dáfídì ni.”+
-