8 Ó ṣe apá Ibi Mímọ́ Jù Lọ,+ gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé náà mu, ó jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́. Ó fi ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) tálẹ́ńtì wúrà tó dára bò ó.+ 9 Ìwọ̀n wúrà fún ìṣó jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì; ó sì fi wúrà bo àwọn yàrá orí òrùlé.