13 Àwọn ará Kálídíà fọ́ àwọn òpó bàbà+ ilé Jèhófà àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù+ àti Òkun bàbà+ tó wà ní ilé Jèhófà sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó àwọn bàbà náà lọ sí Bábílónì.+
17 Gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òpó náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjìdínlógún (18),+ bàbà ni wọ́n fi ṣe ọpọ́n tó wà lórí rẹ̀; gíga ọpọ́n náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta, bàbà ni wọ́n fi ṣe àwọ̀n àti àwọn pómégíránétì tó yí ọpọ́n náà ká.+ Òpó kejì àti àwọ̀n rẹ̀ sì dà bíi ti àkọ́kọ́.
21 Ní ti àwọn òpó náà, gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjìdínlógún (18), okùn ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjìlá (12) lè yí i ká;+ ìnípọn rẹ̀ jẹ́ ìbú ìka* mẹ́rin, ihò sì wà nínú rẹ̀.