ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 7:15-22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Ó mọ òpó bàbà méjì;+ gíga òpó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún (18), okùn ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjìlá (12) lè yí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òpó náà ká.*+ 16 Ó fi bàbà rọ ọpọ́n méjì sórí àwọn òpó náà. Gíga ọpọ́n kìíní jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga ọpọ́n kejì sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. 17 Ó fi ẹ̀wọ̀n ṣe iṣẹ́ ọnà tó dà bí àwọ̀n sórí ọpọ́n tó wà lórí òpó kọ̀ọ̀kan;+ méje sára ọpọ́n kìíní àti méje sára ọpọ́n kejì. 18 Ó ṣe ìlà méjì pómégíránétì yí àwọ̀n náà ká láti bo ọpọ́n tó wà lórí òpó náà; ohun kan náà ni ó ṣe sí ọpọ́n méjèèjì. 19 Àwọn ọpọ́n tó wà lórí àwọn òpó ibi àbáwọlé* náà ní iṣẹ́ ọnà lára, èyí tó dà bí òdòdó lílì, tí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. 20 Àwọn ọpọ́n náà wà lórí òpó méjì náà, àwọ̀n sì wà lára ibi tó rí rogodo lápá ìsàlẹ̀ ọpọ́n náà; igba (200) pómégíránétì sì wà lórí àwọn ìlà tó yí ọpọ́n kọ̀ọ̀kan ká.+

      21 Ó ṣe àwọn òpó ibi àbáwọlé* tẹ́ńpìlì.*+ Ó ṣe òpó apá ọ̀tún,* ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jákínì,* lẹ́yìn náà, ó ṣe òpó apá òsì,* ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bóásì.*+ 22 Iṣẹ́ ọnà tó dà bí òdòdó lílì wà lórí àwọn òpó náà. Bí iṣẹ́ àwọn òpó náà ṣe parí nìyẹn.

  • 2 Àwọn Ọba 25:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òpó náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjìdínlógún (18),+ bàbà ni wọ́n fi ṣe ọpọ́n tó wà lórí rẹ̀; gíga ọpọ́n náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta, bàbà ni wọ́n fi ṣe àwọ̀n àti àwọn pómégíránétì tó yí ọpọ́n náà ká.+ Òpó kejì àti àwọ̀n rẹ̀ sì dà bíi ti àkọ́kọ́.

  • 2 Kíróníkà 4:11-13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Hírámù tún ṣe àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì àti àwọn abọ́.+

      Bẹ́ẹ̀ ni Hírámù parí iṣẹ́ tó ṣe fún Ọba Sólómọ́nì ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, ìyẹn:+ 12 àwọn òpó méjèèjì+ àti àwọn ọpọ́n tó rí bí abọ́ lórí òpó méjèèjì; iṣẹ́ ọnà méjèèjì+ tó dà bí àwọ̀n tó fi bo ọpọ́n tó rí bí abọ́ lórí àwọn òpó náà; 13 ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) pómégíránétì+ fún iṣẹ́ ọnà méjì tó dà bí àwọ̀n, ìlà méjì pómégíránétì fún iṣẹ́ ọnà kọ̀ọ̀kan tó dà bí àwọ̀n, tó fi bo ọpọ́n méjèèjì tó rí bí abọ́ lórí àwọn òpó;+

  • Jeremáyà 52:22, 23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Bàbà ni wọ́n fi ṣe ọpọ́n tó wà lórí rẹ̀; gíga ọpọ́n kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún;+ bàbà ni wọ́n fi ṣe àwọ̀n àti àwọn pómégíránétì tó yí ọpọ́n náà ká. Òpó kejì dà bíi ti àkọ́kọ́ gẹ́lẹ́, bákan náà sì ni àwọn pómégíránétì rẹ̀. 23 Àwọn pómégíránétì mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún (96) ló wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ rẹ̀; lápapọ̀, gbogbo pómégíránétì tó yí àwọ̀n náà ká jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100).+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́