-
2 Kíróníkà 4:11-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Hírámù tún ṣe àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì àti àwọn abọ́.+
Bẹ́ẹ̀ ni Hírámù parí iṣẹ́ tó ṣe fún Ọba Sólómọ́nì ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, ìyẹn:+ 12 àwọn òpó méjèèjì+ àti àwọn ọpọ́n tó rí bí abọ́ lórí òpó méjèèjì; iṣẹ́ ọnà méjèèjì+ tó dà bí àwọ̀n tó fi bo ọpọ́n tó rí bí abọ́ lórí àwọn òpó náà; 13 ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) pómégíránétì+ fún iṣẹ́ ọnà méjì tó dà bí àwọ̀n, ìlà méjì pómégíránétì fún iṣẹ́ ọnà kọ̀ọ̀kan tó dà bí àwọ̀n, tó fi bo ọpọ́n méjèèjì tó rí bí abọ́ lórí àwọn òpó;+ 14 kẹ̀kẹ́ ẹrù* mẹ́wẹ̀ẹ̀wá àti bàsíà mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tó wà lórí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù náà;+ 15 Òkun náà àti akọ màlúù méjìlá (12) tó wà lábẹ́ rẹ̀;+ 16 àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn àmúga+ àti gbogbo àwọn nǹkan èlò wọn ni Hiramu-ábífì+ fi bàbà dídán ṣe fún Ọba Sólómọ́nì fún ilé Jèhófà. 17 Agbègbè Jọ́dánì ni ọba ti rọ wọ́n ní ilẹ̀ amọ̀ tó ki, èyí tó wà láàárín Súkótù+ àti Sérédà.
-