-
Ẹ́kísódù 25:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Kí àwọn kérúbù náà na ìyẹ́ wọn méjèèjì sókè, kí wọ́n fi bo ìbòrí náà,+ kí wọ́n sì dojú kọra. Kí àwọn kérúbù náà sì máa wo ìbòrí náà.
-
-
2 Kíróníkà 5:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù náà nà jáde sórí ibi tí Àpótí náà wà, tó fi jẹ́ pé àwọn kérúbù náà bo Àpótí náà àti àwọn ọ̀pá rẹ̀+ láti òkè. 9 Àwọn ọ̀pá náà gùn débi pé a lè rí orí wọn láti Ibi Mímọ́ ní iwájú yàrá inú lọ́hùn-ún, ṣùgbọ́n a kò lè rí wọn láti òde. Wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí. 10 Kò sí nǹkan míì nínú Àpótí náà àfi wàláà méjì tí Mósè kó sínú rẹ̀ ní Hórébù,+ nígbà tí Jèhófà bá àwọn èèyàn Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú+ bí wọ́n ṣe ń jáde bọ̀ láti Íjíbítì.+
-