24 àwọn àti gbogbo orílẹ̀-èdè máa sọ pé, ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí?+ Kí ló fa ìbínú tó le, tó kàmàmà yìí?’ 25 Wọ́n á wá sọ pé, ‘Torí pé wọ́n pa májẹ̀mú Jèhófà+ Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn tì ni, èyí tó bá wọn dá nígbà tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+